Ikunlẹ abiyamọ o! Awọn mẹwaa tun ṣofo ẹmi lọjọ kẹta Keresi lọna Eko si Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 27, 2022

Ikunlẹ abiyamọ o! Awọn mẹwaa tun ṣofo ẹmi lọjọ kẹta Keresi lọna Eko si Ibadan


Adura ti wọn maa n gba wi pe 'ki Ọlọrun ma jẹ rin lọjọ ti ebi n pa ọna', ati eyi ti wọn maa n gba pe 'ki Ọlọrun ma jẹ ki wọn fi wa palẹ ọdun mọ' ko gba rara f'awọn mẹwaa kan ti a gbọ pe wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto lọjọ kẹta si ọdun keresimesi to kọja lọ.
 
Nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee la gbọ pe ijamba naa waye lopopona marọsẹ Eko si Ibadan, nibi ti eeyan mẹfa tun ti farapa yannayanna.

Gẹgẹ bi alakoso eto irinni fun ajọ ẹṣọ oju popona ti Federal Road Safety Corps (FRSC), ẹka t'ipinlẹ Ọyọ, Joshua Adekanye ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin, o ni agbegbe Guru Mahajji nijamba naa ti waye, to si ba ni lọkan jẹ pupọ.
 
Adekanye sọ pe tirela kan to n ko ẹru lo fi ọna rẹ silẹ, to si lọ gba ọna ọlọna. 
 
O ni ibi ti awakọ bọọsi akero ti nọmba idanimọ rẹ jẹ TRK 135 ZY, eyi to n bọ lati ilu Malumfasi, ipinlẹ Katsina n gbiyanju lati ya fun un, lo ṣeesi kọlu ẹru to gbe sẹyin, to si gbokiti sonu igbo.
 
Loju ẹsẹ lo sọ pe awọn mẹwaa ti jade laye, ti awọn mẹfa si farapa kọja sisọ.

A gbọ pe tirela naa ko duro lati wo ọṣẹ to ṣe, iyẹn ijamba to da silẹ, ko to di pe o na papa bora.
 
Ọkunrin ni gbogbo awọn mejidinlogun ti a gbọ pe wọn kagbako ninu ijamba naa
 
Ọsibitu Ibadan la gbọ pe wọn ko awọn to farapa lọ fun itọju, nigba ti wọn ko awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu Adeọyọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI