Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu eto ẹkọ ọfẹ fun gbogbo awọn agbẹjọro tuntun ti wọn ṣẹṣẹ pe sinu ẹgbẹ.
Ọjọru, Wẹside ana ni kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ agba, Ọmọwe Alabi Afees Abọlọrẹ sọrọ naa, to si ni ijọba oun yoo tubọ maa ṣe iranlọwọ fawọn ọdọ.
AbdulRazaq ni gbogbo awọn ti wọn ṣẹṣẹ peregede sinu ẹgbẹ agbẹjọro lorileede Naijiria, iyẹn awọn to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ni anfaani yii wa fun.
Nigba to n ki awọn akẹkọọ tuntun naa, Ọmọwe Abọlọrẹ sọ pe ìjọba ipinlẹ naa ti kan an nipa lati rii pe eto igbayegbadun awọn akẹkọọ jẹ ohun logun, ti wọn si n ṣe ẹtọ fun wọn.
Nibẹ lo ti gba wọn lamọran wi pe ki wọn ma ṣe fi iṣẹ naa ṣe ohun ti ko tọ.
No comments:
Post a Comment