Eyi ni aṣiri iku to pa Pẹlẹ, agba agbabọọlu agbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 30, 2022

Eyi ni aṣiri iku to pa Pẹlẹ, agba agbabọọlu agbaye


Gbajugbaja agba agbabọọlu agbaye nni, Pẹlẹ ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọrin, 82.

Ọsibitu Albert Einstein to wa niluu Sao Paulo la gbọ pe Pẹlẹ ku si l'Ọjọbọ, Tọsidee lẹyin aisan rampẹ

Aisan jẹjẹrẹ ti awọn oloyinbo n pe ni Cancer ni iroyin fi to wa leti wi pe Pẹlẹ ti n koju lati bi ọdun meloo kan sẹyin ko to di pe ẹlẹmi pada gba a.

Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni Pẹlẹ to gba ife ẹyẹ agbaye, iyẹn World Cup, eyi ti ko tun tii sẹni to ni iru rẹkọọdu bẹẹ.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Pẹlẹ wa nigba to gba ife ẹyẹ akọkọ fun orileede Brazil, iyẹn lọdun 1958, nibi to ti gba aami ayo meji wọle ninu aṣekagba ifigagbaga ti ife ẹyẹ agbaye pẹlu orileede Sweden.

Ori ikanni ayelujara ti Twitter to jẹ ti Pẹlẹ fúnra rẹ ni wọn tun ti kede iku rẹ ni ọsan ana, Tọsidee

    No comments:

    Post a Comment

    PÍN-IN KÁÀKIRI