Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti fi da gbogbo ọmọ orileede Naijiria loju wi pe bi oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa, Peter Obi ba fi le jawe olubori, wọn yoo sọ owo to kere julọ t'awọn oṣiṣẹ n gba di ẹgbẹrun lọna ọgọrin si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira l'oṣu.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu Labour gbe awọn ipinnu wọn sita, lori awọn awọn anfaani ti wọn fẹẹ ṣe f'awọn araalu sita, nibi ti wọn ti sọ pa wakati lawọn oṣiṣẹ yoo maa gba owo wọn, dipo oṣu ti wọn n gba tẹlẹ.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels ninu eto Sunrise Daily to waye laarọ oni, Ọjọbọ, Tọsidee, igbakeji alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Ayọ Ọlọrunfẹmi sọ pe ẹgbẹ naa n woye ẹgbẹrun lọna ọgọrin si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, eyi to yatọ si ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo ti oṣiṣẹ n gba bayii.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Iṣẹ ti onikaluku ba n ṣe ni yoo sọ iye owo ti yoo maa gba. Bi apẹẹrẹ, awọn to n ru biriṣope n gba ẹgbẹrun meji aabọ sii ẹgbẹrun mẹta naira lojumọ, eyi ko tii dara to gẹgẹ bi ilana yii ṣe wa.
“Bi ẹ ba pin ẹgbẹrun mẹta naira si wakati mẹfa, o jẹ pe ẹẹdẹgbẹta naira ni wọn n gba laaarin wakati kan.
“Fun idi eyi, bi ẹ ba pin in si eyi to wa nilẹ lakoko yii, o daju pe a ma maa sọrọ ẹẹdẹgbẹta naira si ẹgbẹrun kan naira laaarin wakati kan, o si wa tun nii ṣe pẹlu iru iṣẹ teeyan ba n ṣe, ati pe lẹyin o rẹyin lojumọ, eeyan yoo le sọ pe oun n gba ẹgbẹrun mẹrin naira lojumọ.
“Bi ẹ ba si wa ṣiro rẹ ni ẹgbẹrun mẹrin fun ogunjọ tabi ọjọ marundinlọgbọn, a n sọrọ nipa ẹgbẹrun lọna ọgọrin si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira l'oṣu.”
No comments:
Post a Comment