David to n fi aṣọ LASTMA lu jibiti l'Ekoo ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 16, 2022

David to n fi aṣọ LASTMA lu jibiti l'Ekoo ti ha o


Afaimọ ni gendekunrin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, David Oluchukwu to n fi aṣọ awọn oṣiṣẹ aabo oju popona t'ipinlẹ Eko ti a mọ si
Lagos State Traffic Management Authority, LASTMA lu awọn araalu ni jibiti ma pada fi aṣọ penpe roko ọba, paapaa bi ọdun keresimesi ṣe n bọ lọna yii.
 
Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii la gbọ pe ọwọ tẹ David lagbegbe lẸkki n'ipinlẹ naa, nibi to ti n dari ọkọ oju popona.
 
Kii ṣe bi David ṣe n dari ọkọ lo mu ki akara rẹ tu s'epo, bi ko ṣe pe bo ṣe n fi aṣọ alaṣọ to jigbe, laini kaadi idanimọ lo tu aṣiri rẹ.
 
Alokoso eto iroyin, AdebayoọTaofiq, ati alakoso ileeṣẹ naa, Bọlaji Ọrẹagba, nigba ti wọn n f'idi iṣẹlẹ ọhun jẹ ko ye wa pe ikọ ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ naa lo rọwọ to David, nibi to ti n gba owo riba lọwọ awọn awakọ.
  
Wọn ni ọkan lara awọn ọdaran paraku to n gba fi ẹtanjẹ gba owo lọwọ awọn araalu ni David, to si ni ọpọ owo ni wọn ti gba lọwọ awọn awakọ alaimọkan.
 
Lara awọn ẹsun ti wọn fi n kan awọn awakọ ti wọn ti mu ni pe wọn ko lo bẹliti idaabobo, gbigba ọna ti ko tọ, gbigbe ọkọ sibi ti ko yẹ, sisare kọja ọkọ lọna ti ko yẹ, ati bẹẹbẹẹlọ.

A gbọ pe ọna ti David gba mura lo fa a ti aṣiri rẹ fi tu si wọn lọwọ. Wọn ni niṣẹ lo wọ aṣọ LASTMA naa sori sokoto dudu, eyi ti kii ṣe unifọọmu wọn, to si n gba owo lọwọ awọn awakọ to n ja ero silẹ lori afara Lẹkii lọna ti ko tọ.
 
David, ọmọ bibi ilu Ukpu nipinlẹ Anambra nigba to n jẹwọ ṣalaye pe owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira loun maa n pa lojumọ nidi iṣẹ naa, to si tọọ aforiji.
 
Alakoso lẹka eto ofin nileeṣẹ LASTMA, Amofin Akerele Kẹhinde, ti wa fidi rẹ mulẹ pe David ti pada foju ba ile-ẹjọ, ni ibamu pẹlu ofin ọdaran ipinlẹ naa l'Ọjọbọ, Tọsidee ana.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI