Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun lo ti bu ọwọ lu iyansipo awọn akọwe agba tuntun marun-un lẹka iṣẹ ijọba.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Kunle Ṣomọrin fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii lo ti sọ pe awọn akọwe agba tuntun naa ni yoo di awọn alafo to ṣi silẹ, ati pe iṣẹ wọn bẹrẹ lai fi akoko ṣofo rara.
Ṣomọrin sọ pe bi awọn ti wọn yan sipo naa ṣe tete de ẹnu iṣẹ, ati oṣuwọn ti wọn gbe, to fi mọ ijafafa ati iha ti wọn kọ si iṣẹ ti wọn gba lo fa a ti wọn fi bu ọwọ lu wọn.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe yiyan ti wọn yan awọn eeyan naa lo lọ nibamu pẹlu iwe ofin orileede Naijiria ti ọdun 1999, iyẹn ni abala 208 (c).
Awọn akọwe agba tuntun naa ni: Onimọ-ẹrọ Ṣakirudeen Ayinde Salaam; Ọgbẹni Adesọji Augustus Adewuyi; Ọgbẹni Hammẹd Morakinyọ Ojo; Ọgbẹni Adeṣina Mufutau Towolawi ati Ọmọwe (Arabinrin) Ọlayinka Nikẹ Ẹlẹmide.
Nigba to n ki wọn ku oriire, Gomna Abiọdun gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, o si ni ki wọn fi ọkan akin gba ipenija ti wọn yoo koju, eyi to maa mu ki wọn gba koriya nigbẹyin.
No comments:
Post a Comment