Kani kii ṣe ori to kọ ọkunrin ọlọkada kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Abel ni, boya ko ba ti d'ẹni igbagbe lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ṣugbọn nitori Ẹlẹdaa ti ko pada lẹyin rẹ, lo jẹ ko ṣi wa loke eepẹ.
Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii la gbọ pe ọwọ tẹ ọkunrin to yan iṣẹ birikila laayo niluu Agọbaba, ijọba ibilẹ Guusu Yewa, ipinlẹ Ogun, Ṣakiru Bello.
A gbọ pe ṣe ni Ṣakiru, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn pe Abel gẹgẹ bi ọlọkada lati gbe oun de agbegbe Agọbaba. Bi wọn ṣe de aarin meji lo sọ fun ọlọkada naa lati ya sinu igbo kan.
Nigba ti wọn yoo fi rin siwaju diẹ, ni Ṣakiru sọ fun Abel pe ko duro nile akọku kan to n kọ lọwọ, nibẹ lo ti lọ fa ṣọbiri yọ, to si fọ mọ ọlọkada naa lori.
Wọn nigba ti ọlọkada ọhun rii pe Ṣakiru fẹẹ pa oun patapata ni, lo jẹ ko dọgbọn lati ṣe bi ẹni to ti ku, eyi to fun Ṣakiru lanfaani lati gbe ọkada naa salọ.
A gbọ pe lẹyin bii wakati meloo kan ni Abel dide, to si gba ọdọ awọn ẹṣọ aabo So-Safe Corps lọ lati fi ẹjọ sun. Ko pẹ rara ti iwadii fi bẹrẹ, ti wọn si pada ri Ṣakiru pẹlu ọkadan ọhun.
Loju ẹsẹ tọwọ ti tẹ ẹ lo ti bẹrẹ sii ka boroboro wi pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun ko mọ pe aṣiri yoo pada tu sita, ti ọwọ yoo si tẹ oun. O ni igba ti iṣẹ birikila toun yan laayo ko fẹẹ pe mọ, lo jẹ koun wa ọna lati ji ọkada gbe.
Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Corps lo jẹ ko ye wa pe agbegbe Penpe to wa niluu Owode Yewa ni Ṣakiry n gbe, nibẹ lo si ti lọ ji ọkada gbe.
Yusuf ni ọga awọn Sọji Ganzallo ti paṣẹ k'awọn mu Ṣakiru ati ọkada naa lọ f'awọn ọlọpaa lati ṣe iwadii siwaju sii nipa iru eeyan to jẹ ko to di pe wọn foju rẹ ba ile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment