Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ọkan agba sọrọsọrọ ori redio nni, Yẹmi Ṣonde, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Jigan Akala ko tii balẹ pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn kan n dunkooko lati yẹyẹ rẹ lori ayelujara.
Yẹmi Sonde, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ YES FM to wa niluu Ibadan lo pariwo sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee wi pe awọn kan n dunkooko lati fi fọto ihooho oun sita fun gbogbo aye lati ri.
O lawọn to wa nidii iwa naa n beere owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira si miliọnu kan aabọ naira lọwọ oun, ki wọn le dẹkun fifi fọto ihooho rẹ sita.
Yẹmi Ṣonde ni awọon wa nidii iwa buruku naa ti pe gbogbo awọn to sunmọ oun lati bawọn sọrọ wi pe ki wọn kilọ foun lati fi owo naa ranṣẹ, bi bẹẹ kọ, awọn yoo gbe fọnran ati fọto ihooho rẹ sita.
Orileede Cote d’Ivoire ni gbajugbaja pedepede naa sọ pe ẹni to n dunkooko mọ oun n gbe, to si loun ti sọ fun ẹni naa wi pe ko lọ ṣe ohun to ba fẹẹ ṣe, nitori toun ko ni owo kankan lati san.
No comments:
Post a Comment