Aye o! Ọwọ tẹ baba agbalagba to n fi ẹjẹ wẹ leti odo l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 15, 2022

Aye o! Ọwọ tẹ baba agbalagba to n fi ẹjẹ wẹ leti odo l'Abẹokuta


Ṣikun bayii lọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ baba agbalagba ẹni ọdun mọkandinlaadọta kan, Ganiyu Ṣhina, ẹni ti wọn sọ pe ẹjẹ lo fi n wẹ leti odo niluu Abẹokuta.
 
Ojule kẹrin, adugbo Ogunji to wa lagbegbe Ọbantoko niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa la gbọ pe Ganiyu n gbe, ṣugbọn eti odo kan to wa lagbegbe Kotopo, ijọba ibilẹ Ọdẹda lọwọ ti tẹ ẹ lakoko to n fi ẹjẹ wẹ lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun 2022.
 
Awakọ taisi ni wọn pe Ganiyu.
 
Ohun ti a gbọ ni pe taisi ni Ganiyu fi n ṣiṣẹ lo gbe lọ seti odo ọhun, ti awọn ara agbegbe naa si rii, ṣugbọn ti wọn ko ri tiẹ ro. Igba ti wọn lo bọ silẹ ninu ọkọ taisi Nissan rẹ, lo fa kanrinkan ibilẹ yọ, to si tun gbe ike to kun fun ẹjẹ pupa jade ninu mọto naa.
 
Wọn ni loju ẹsẹ lo ti bẹrẹ sii fi ẹjẹ ati kanrinkan naa wẹ. Bo ṣe n wẹ iwẹ naa lọwọ, lo ṣakiyesi wi pe awọn eeyan ti ri oun. Wọn ni oju ẹsẹ lawọn to wa nibẹ ti gbiyanju lati lọ ba a.
 
Igba ti wọn loo rii pe awọn eeyan ti n sare bọ lati wa ba oun, lo ba fi ẹsẹ fẹẹ, ṣugbọn ti wọn pada lee mu.
 
Ni kete tọwọ tẹ ẹ la gbọ pe wọn ti ranṣẹ sawọn ọlọpaa ẹkun Arẹgbẹ lati wa a wo nnkan ti oju wọn ri, ti awọn ọlọpaa si pada mu lọ teṣan wọn, nibi ti wọn ti lọ fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to fi iroyin ọhun sita nirọlẹ oni ṣalaye pe nigba ti baba naa n jẹwọ ni teṣan ọlọpaa, o ni babalawo lo sọ foun lati lọ fi ẹjẹ wẹ leti odo, ati pe ẹjẹ naa kii ṣe ẹjẹ eeyan, bi ko ṣe ẹjẹ maluu.
 
Ganiyu sọ pe awọn aye lo n ba oun finra, toun si lọ silẹ babalawo lati gba itọju.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, Lanre Bankọle to jẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo ẹjẹ naa nile iwosan lati mọ boya ẹjẹ eeyan ni tabi ti ẹranko ko to di pe wọn gbe igbesẹ to yẹ lee lori.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI