Awọn telọ gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq, gomina Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 24, 2022

Awọn telọ gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq, gomina Kwara


Laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn aranṣọ, iyẹn Telọ kaakiri ipinlẹ Kwara gbe oṣuba kare fun gomina ipinlẹ naa, Malaamu AbdulRahman AbdulRazaq nibi akanṣe eto ti wọn ti yan awọn oloye tuntun.
 
Bẹ o ba gbagbe, awọn telọ wọnyi ni gomina ke si lasiko rogbodiyan ajakale arun korona to bẹ silẹ lọdun 2020 lati ṣe awọn aṣọ iboju-bomu lọpọ yanturu, eyi ti yoo daabo bo araalu lọwọ ajakalẹ arun korona naa.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee la gbọ pe eto naa waye niluu Ilọrin to jẹ olu-ilu ipinlẹ Kwara, nibi ti ẹgbẹ awọn telọ naa ti yan awọn oloye tuntun ti yoo tukọ ẹgbẹ wọn fun saa miran.
 
Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni Kọmiṣanna fọrọ eto ileeṣẹ ati imọ tẹkinọlọji (Business, Innovation and Technology), Ọnarebu Ibrahim Akaje; oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ akanṣe iṣẹ, Alaaji Abdulrazaq Jiddah ati Ọmọọba Suleiman Abubakar Sai Kayi, toun jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ oṣelu.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI