Awọn eeyan ko mọ pe oyun lo jabọ lara mi, wọn ro pe mọ kan sanra lasan mi - Toyin Abraham - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 12, 2022

Awọn eeyan ko mọ pe oyun lo jabọ lara mi, wọn ro pe mọ kan sanra lasan mi - Toyin Abraham


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Toyin Aimakhu tabi Toyin Abraham ti sọ pe ọpọ awọn to n bu ẹnu atẹ lu boun ṣe tobi ni wọn ko mọ iṣoro toun n koju, idi ree toun ko ṣe sọ ohunkohun nigba ti wọn gbe iroyin jade nipa oun ati idile oun.
 
Toyin, ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Mama Ire sọ pe ko tii pẹ pupọ ti oyun to yẹ koun fi bimọ keji fun ọkọ oun jabọ, to si jẹ nnkan to ba oun lọkan jẹ pipọ.

Ilu-mọ-ọn-ka oṣebinrin naa lo tu aṣiri yii lori ẹrọ amohunmaoran ti ileeṣẹ Channels, iyẹn lori eto 'Rubbin minds with Ebuka Obi-Uchendu'.

O ni ọpọ awọn eeyan lo n beere wi pe igba wo loun yoo bimọ keji le Ire, to si ni asiko Ọlọrun loun n duro de.

Nibi ifọrọwerọ naa lo ti sọ pe oun ko jẹ ki gbogbo eebu ti wọn n bu oun ko soun lori, nitori pe lara awọn ipenija to maa n koju awọn gbajugbaja oṣere niyẹn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI