Awọn aafa agbaye rọjo adura ara-ọtọ le Gomina AbdulRazaq lori n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 4, 2022

Awọn aafa agbaye rọjo adura ara-ọtọ le Gomina AbdulRazaq lori n'Ilọrin


Beeyan ba wa nibi ti awọn agba aafa kaakiri agbaye to f'iluu Ilọrin ṣe ibugbe ti n rọjo adura le gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lori, yoo mọ pe tọkantọkan ni wọon n ṣe e, kii ṣe oju aye ni wọn n ṣe.
 
Ko si nnkan meji to si fa a, bi kii ṣe bi wọn ṣe ṣapejuwe gomina wọn gẹgẹ bii ẹnikan to da yatọ laaarin awọn gomina lagbaye, paapaa lorileede Naijiria.
 
Wọn ni gomina to n mu ileri rẹ ṣẹ lai wo ti ẹlẹyamẹya, ati pe idagbasoke ati ilọsiwaju to ti mu ba ipinlẹ naa ko le jẹ ki wọn fi oju oloore rẹ gun igi.
 
Nibi idije kika Kuraani to waye niluu Ilọrin l'ọjọ Abamẹta, Satide to kọja ni awọn agba aafa naa ti sọrọ yii jade, ti wọn si loo di dandan lati fi adura ran an lọwọ, ko le pada s'ipo naa lẹẹkeji.
 
AWIKONKO gbọ pe lara awọn idi pataki ti awọn olori ẹlẹsin naa fi pinnu lati gbadura ara-ọtọ fun gomina ni bi wọn ṣe lo tete de s'ibi gbagede aṣekagba ayẹyẹ kika Kuraani naa, eyi ti wọn ni ijọba Kwara ṣagbatẹru rẹ ni papa iṣere Ilọrin.
 
Wọn ni eto naa ko tii bẹrẹ ti Gomina AbdulRazaq ti debẹ, eyi to ya awọn eeyan lẹnu, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe iru rẹ ko ṣẹlẹ ri latigba ti wọn ti bẹrẹ eto ọhun.
 
Eto ọhun ti Imaamu AbdulMumin Afodun dari rẹ lo paṣẹ pe ko bẹrẹ ni kete ti gomina debẹ, to si ni Gomina AbdulRazaq ni gomina akọkọ ti yoo wa sibi eto naa fun ọdun meji lera wọn latigba ti wọn ti bẹrẹ.
 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI