Ata gigun l'awọn eleyii fẹ si ọlọkada loju l'Agọ Iwoye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 7, 2022

Ata gigun l'awọn eleyii fẹ si ọlọkada loju l'Agọ Iwoye


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin mẹta kan ti wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ, ati pe ọkada ni wọn fẹran lati maa ja gba lọwọ awọn to ba nii.
 
Ọjọ karun-un, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni iroyin fi to wa leti pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ awọn mẹtẹẹta ti wọn pe orukọ wọn ni Daniel Akapo, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn; Idowu Ajao Sunday, ọmọ ogun ọdun ati Dare Oluṣẹgun, ọmọ ọdun mẹrinlelogun.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn l'awọn adigunjale lo pe ọlọkada ti wọn pe ni Ṣẹfiu Mọshood lati gbe wọn lọ sagbegbe Abule Oke Ẹrigba niluu Agọ-Iwoye. Bi wọn ṣe de agbegbe kan nitosi igbo, ni wọn sọ fun ọlọkada naa lati duro fun wọn, ati pe awọn ko lọ mọ.
 
Bo ṣe duro ni wọn ti ki ọwọ bọ apo pẹlu ẹtanjẹ lati yọ owo jade fun un, lai mọ pe ata gigun ni wọn yọ, ti wọn si fẹẹ si ọlọkada naa loju, ki wọn le raaye gbe ọkada rẹ salọ. 

Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ọlọkada naa ti ba wọn wọya ija, ti wọn si ni aake ṣeeṣi jabọ ninu baagi wọn, eyi ti ọlọkada naa mu lati fi koju wọn.

Nibi ti wọn ti jọ n fa ọrọ yii ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti debẹ, ti wọn si ko awọn mejeeji. Teṣan ọlọpaa ti wọn ko Daniel ati Idowu tọwọ tẹ lọ ni wọn ti tu aṣiri wi pe Dare lo ran wọn niṣẹ lati lọ ja ọkada gba, eyi lo jẹ ki wọn lọ gbe e.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe iwadii awọn mẹtẹẹta daadaa, ki wọn si foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to ba tọ si wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI