Oludije sipo aṣofin ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Ọlawale Oshọla Fadipẹ ti sọ ọ sita gbangba wi pe Oloye Olumide Aderinokun nikan ni oludije to kaju oṣuwọn lati du ipo aṣofin lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.
Olumide Aderinokun ni ondije du ipo aṣofin agba lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Fadipẹ ni eeyan araalu ni Aderinokun, to si ni oju aanu ati ofẹ araalu lọkan, koda to ni oun ni ẹnikan ṣoṣo to yẹ lati gba ipo aṣofin lọwọ Sẹnetọ Ibikunle Amosun.
"Bo tilẹ jẹ pe mi o si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa pẹlu Oloye Olumide Aderinokun, ẹni to n du ipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣugbọn mo maa rii daju pe mo polongo ibo fun wọn.
"Gbogbo awọn alatilẹyin mi patapata ni maa sọ fun pe ki wọn dibo fun Aderinokun lọdun 2023.
"Mo ti mu yin gẹgẹ bii ẹgbọn mi bayii, o si da mi loju pe ẹ ko nii ja awọn eeyan kulẹ. Mo fi n da awọn eeyan mi ninu ẹgbẹ wa loju wi pe Aderinokun la maa tẹle nitori pe a ko ni oludije fun ipo naa.
"Bakan naa mo fi n da a yin loju pe Aderinokun ni gbogbo awọn eeyan mi maa dibo fun lọdun 2023, ki iṣẹ aarin gbungbun ipinlẹ Ogun le tubọ kẹsẹjari."
Fadipẹ lo n jade du ipo aṣofin lati agbegbe Ọdẹda.
No comments:
Post a Comment