Lopin ọsẹ to tan yii ni awọn oṣiṣẹ ijọba to ṣe daadaa julọ lẹnu iṣẹ n'ipinlẹ Kwara jeere iṣẹ ọwọ wọn, nigba ti ijọba bẹrẹ sii fun wọn ni ẹbun to jọju.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gbe ẹbun ọlọkan-o-jọkan f'awọn oṣiṣẹ ijọba to yọranti lẹnu iṣẹ wọn, iyẹn awọn to n ṣe deedee lẹnu iṣẹ ti wọn gba.
Nibẹ ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fa kọkọrọ ọkọ bọginni le oṣiṣẹ kan pataki to peregede julọ laaarin awọn akẹgbẹ rẹ, Dokita Kazeem Lakadir lọwọ.
AbdulRazaq nigba to n sọrọ dupẹ gidigidi lọwọ awọn oṣiṣẹ patapata, to si loun ko nii dawọ duro lato maa ṣe ojuṣe oun fun wọn, toun yoo si tun maa gbe eto koriya kalẹ fun wọn.
Eto naa ti wọn pari eto ọsẹ awọn oṣiṣẹ, iyẹn Kwara State Civil Service Week, nibi aṣekagba rẹ ti wọn ti jẹ ounjẹ alẹ ati gbigba awọọdu, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaide.
Dọkita Lakadir, ọkan lara awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba, ẹka ti eto ilera la gbọ pe o kun oju oṣuwọn gidi laaarin gbogbo awọn oṣiṣẹ n'ipinlẹ naa, ti wọn si ni igbimọ ti wọn yan lo fa ọkunrin naa kalẹ lai ṣe ojusaaju.
No comments:
Post a Comment