Aadọta alẹnulọrọ fẹẹ gba awọọdu ni Kwara l'ọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 22, 2022

Aadọta alẹnulọrọ fẹẹ gba awọọdu ni Kwara l'ọsẹ yii


Ṣe ọrọ Yoruba kan to sọ pe 'inu didun lo n mu koriya wa' gan-an lo lọ nibamu pẹlu bi ijọba ipinlẹ Kwara ṣe fẹẹ fi aami ẹyẹ da awọn alẹnulọrọ ti ko wọpọ lọla kaakiri ipinlẹ naa.
 
Kii ṣe pe ijọba Kwara kan fẹẹ da awọn eeyan naa lọla lasan, bi ko ṣe ipa ti wọn ko ninu eto idagbasoke ipinlẹ naa lo fa a, ti wọn fi fẹẹ fi ẹmi imoore han si wọn, ati lati mu k'awọn miran le sa ipa wọn lori bi ipinlẹ naa yoo ṣe maa lewaju ni gbogbo igba. 
 
Oniruuru ẹka iṣẹ kaakiri agbaye la gbọ pe ijọba Kwara ti yan awọn to n gbe orukọ ipinlẹ naa ga lati da wọn lọla rẹpẹtẹ, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 
A gbọ pe bi awon to wa laye yoo ṣe gba aami ẹyẹ, naa ni wọn ko tun ni gbagbe awọn to ti fi ilẹ ṣaṣọbora naa pẹlu, lati fi mọ riri ipa ti ko lakoko ti wọn wa laye.

Ọna marundinlọgbọn la gbọ pe eto aami ẹyẹ, iyẹn awọọdu naa pin si, ti a si gbọ pe wọn yan awọn to yẹ gẹgẹ bi ipa ti wọn ko ninu ilọsiwaju ati idagbsoke ipinlẹ ọhun.
 
Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin to pe laipẹ yii, ṣaaju ọjọ eto naa, Kọmiṣanna fọrọ eto ikansira-ẹni, Abubakar Saddiq Buhari jẹ ko di mimọ pe ko si ojusaaju ninu bi wọn ṣe yan awọn ti yoo gba aami ẹyẹ, nitori pe iṣẹ onikaluku lo n sọrọ fun un.

 
Lara awọn to wa nibi ipade awọn akọroyin naa ni Kọmiṣanna fọrọ eto agba ati idagbasoke igberiko, Abdullateef Alakawa; Alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ ere idaraya, Bọlakalẹ Magaji; Alakoso ileeṣẹ Ilorin Innovation Hub, Temi Kọlawọle; Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ awọn akẹkọọ, Mubaarak Bello; Mohammed Usman ti ileeṣẹ KW-IRS; ati Alaga ẹgbẹ Education Secretaries Forum, Oloye Lere Balogun.
 
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ori ikanni ayelujara ti wọn ti pese silẹ tipẹ lawọn eeyan yoo ti dibo f'awọn to ba yẹ, ati pe aago mejila ọsan oni, Ọjọbọ, Tọsidee ni eto idibo ọhun yoo kasẹ nilẹ, nibi ti wọn yoo ti mu awọn to jawe olubori.
 
Ayẹyẹ ọhun yoo si waye ninu gbọngan Atlantic to wa niluu Ilọrin lọjọ Furaidee to n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI