A ko nii dẹkun lati maa ṣe iranwọ f'awọn olokoowo kekeeke ni Kwara - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 14, 2022

A ko nii dẹkun lati maa ṣe iranwọ f'awọn olokoowo kekeeke ni Kwara - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana ti ṣe ileri wi pe ijọba oun ko nii dẹkun lati maa ṣe iranwọ f'awọn olokoowo kekeeke nipinlẹ naa, loju naa lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wọn.

Nibi ti gomina ti ṣiṣọ loju ipatẹ ọja agbaye ti wọn pe ni Trade Fair, ẹlẹẹkẹsan iru ẹ, eyi to n waye niluu Ilọrin to jẹ olu-ilu ipinlẹ Kwara ni AbdulRazaq ti sọrọ idaniloju yii.

AbdulRazaq ni gbogbo awọn ileeṣẹ kereje-kereje ti a mọ si Small and Medium Enterprises loun yoo ma gbe eto iranwọ kalẹ fun wọn, lati le jẹ ki wọn dagbasoke nipa okoowo ti wọn yan laayo, eyi ti yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje Kwara.

O ni ipenija nla lo n ba idagbasoke awọn okoowo kereje, to fi mọ ileeṣẹ nla-nla, nitori pe awọn kan ti a n lo lorileede Naijiria pọ ju eyi ti wọn n ṣe jade lọ, to si n ṣakoba fun eto ọrọ aje.

Bẹẹ lo ni bo tilẹ jẹ pe epo rọbii ati afẹfẹ gaasi jẹ ohun kan to n ṣe daadaa ninu idagbasoke eto ọrọ aje lorileede yii, sibẹ anfaani tun wa ninu awọn ohun ti a n ṣe jade lati orileede yii, to si rawọ ẹbẹ s'ijọba apapọ lati gbe eto iranwọ dide f'awọn araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI