Gbogbo eto lo ti pari fun gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati ṣiṣọ logun eegun ile ẹgbẹ fun ipolongo idibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti Tunde Ọladunjoye, ẹni to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ APC n'ipinlẹ Ogun fi sita nirọlẹ oni, Ọjọbọ, Tọsidee lo ti sọ pe alakoso eto ipolongo idibo nipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun ti pari gbogbo eto.
Ọladunjoye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun 2023 ni eto ọhun yoo waye niwaju ọfiisi gomina to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta.
Bakan naa lo tun sọ pe Dapọ Abiọdun yoo tun lo anfaani naa lati fi oju awọn igbimọ ipolongo naa han f'awọn eeyan lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment