Wọn ti ri ọmọ kekere ti wọn jigbe l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 18, 2022

Wọn ti ri ọmọ kekere ti wọn jigbe l'Ekoo


Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede sita wi pe awọn ti ri ọmọdekunrin kan,
Emmanuel Timilẹhin Adeleke ti awọn ajinigbe jigbe, ṣugbọn ti ori rẹ ko pada gbabọdi.
 
Gẹgẹ bi Benjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa Eko ṣe ṣalaye, o ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko tii le sọ pato ibi ti ọmọ naa ti wa, paapaa agbegbe ti wọn ti jiigbe, sibẹ o ni iwadii ti n lọ lọwọ.
 
Hundeyin sọ pe gbogbo ibeere t'awọn n beere lọwọ rẹ jọ bi ẹni pe ko mọ nnkan to n ṣe, ṣugbọn o fi ye wa pe ọmọ naa ko ju ọmọ ọdun mọkanla si mẹrinla lọ.

Agbegbe Jakande to wa ni Ikọtun ni ọmọ naa sọ pe wọn ti ji oun gbe l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Benjamin wa rawọ ẹbẹ s'awọn eeyan pe bi wọn ba mọ awọn ọmọ ọhun, ki wọn tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, lati le daa pada f'awọn obi rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI