Ọjọ Jimọ to kọja yii ko fi bẹẹ dun fun olori ile igbimọ aṣofin agba orileede yii tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki, pẹlu bi a ṣe gbọ pe wọn yẹyẹ rẹ nibi irun Jimọ to waye niluu Ilọrin to jẹ olu-ilu ipinlẹ Kwara.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ṣalaye pe ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe aga olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, iyẹn Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ti wọn sọ pe Saraki lọ jokoo si, eyi ti wọn l'awọn to pese aga naa lee dide lai woju ẹ.
Wọn ni bi Saraki ṣe de mọṣalaṣi agba tiluu Ilọrin, iyẹn Ilorin Central Mosque fun ti irun jumaati ọjọ Jimọ, aaye ti wọn pese silẹ fun Ọjọgbọn Gambari ni sọ pe Saraki lọ jokoo si, koda, a gbọ pe orukọ Gambari wa lori aga ọhun.
Wọn ni loju ẹsẹ ti awọn to pese aaye naa silẹ ti rii pe Saraki jokoo sibẹ, ni wọn ti lọ ba a lati dide, ṣugbọn ti wọn lo sọ fun wọn pe wọn ko ni ẹtọ lati gbe oun dide kuro nibẹ.
Fun ibi ọpọlọpọ iṣẹju la gbọ pe wọn fi fa ọrọ yii, ko to di pe Saraki gba lati dide kuro nibẹ, bo tilẹ jẹ pe ohun ti wọn ni Saraki sọ tẹlẹ ni pe ki wọn lọ wa ibomiran fun Ọjọgbọn Gambari lati jokoo si, nitori pe agba alẹnulọrọ loun nipinlẹ naa, ṣugbọn sibẹ, wọn ko gbọ ọrọ rẹ, ti wọn fi lee dide.
No comments:
Post a Comment