Iroyin ayọ lo tun wọle fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lapapọ lori bi ajọ to n ṣe iranwọ fun iṣẹlẹ pajawiri lorileede yii, National Emergency Management Agency (NEMA) ṣe fi ounjẹ at'awọn ohun elo ranṣẹ si ipinlẹ naa, f'awọn to kagbako nibi iṣẹlẹ ijamba omiyale to ṣẹlẹ laipẹ yii.
Ọjọbọ, Tọside to kọja yii la gbọ pe ajọ NEMA wọ olu-ilu Ilọrin tii ṣe ipinlẹ Kwara lati ge awọn ounjẹ at'awọn ohun elo fun ijọba ipinlẹ naa, lati pin-in f'awọn to padanu dukia wọn sinu ijamba omiyale ati awọn awọn ajalu miran lọdun 2022.
Nigba to n sọrọ, alakoso agba fun ajọ NEMA, Mustapha Ahmẹd sọ pe inu oun dun pe iwadii ti ileeṣẹ Humanitarian Affairs, Disaster Management and Social Development ṣe ko ṣe ojusaaju rara, eyi to mu ki aarẹ dide iranwọ.
O ni ẹgbẹrun mejila '12,000 metric tons' ounjẹ bii irẹsi ni wọn ya sọtọ f'awọn eeyan.
No comments:
Post a Comment