Ohun ini nla l'awọn oṣiṣẹ jẹ - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 7, 2022

Ohun ini nla l'awọn oṣiṣẹ jẹ - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRahman ti ṣapejuwe awọn  oṣiṣẹ n'ipinlẹ naa gẹgẹ bi ohun ini nla ti ijọba jogun, to si jẹ ko di mimọ pe o di dandan lati tọju wọn.
 
AbdulRazaq sọ pe awọn oṣiṣẹ dabi taya to n gbe ọkọ rin, nitori pe wọn n ko ipa to pọ, to si jọju ninu eto idagbasoke ati ilọsiwaju eto ọrọ aje ilu, eyi to ni wọn ko ṣee fi ṣere rara.
 
Nibi ifọrọwerọ ti AbdulRazaq ṣe pẹlu awọn ileeṣẹ iroyin mẹta to jẹ ti ipinlẹ naa lo ti jẹ ko di mimọ, to si ni ọjọ iwaju ati ipinnu rere loun ni f'awọn oṣiṣẹ, nitori pe wọn gbọdọ maa jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.

Nigba ti wọn n beere pe ko sọrọ lori bi yoo ṣe da awọn oṣiṣẹ meloo kan duro, o ni irọ nla to jinna si otitọ ni, ko si le fẹsẹ mulẹ.
 
“Inu awọn oṣiṣẹ n dun si wa pupọ. A ko nilo lati le ẹnikẹni danu. A ti gbiyanju lati maa na iye owo to n wọle fun wa nipa sisan owo oṣu lasiko to yẹ. Wọn kii ṣe ajaga fun ipinlẹ yii. A ko ni aawọ, ibi ti kidiẹkudiẹ wa ni ti owo tijọba ana jẹ wọn, a si ti n gbe igbesẹ lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI