Nitori Ataọja ti wọn fẹẹ rọ l'oye, awọn araalu fẹhonuhan l'Oṣogbo, wọn l'awọn ko nii gba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 10, 2022

Nitori Ataọja ti wọn fẹẹ rọ l'oye, awọn araalu fẹhonuhan l'Oṣogbo, wọn l'awọn ko nii gba


Gbogbo awọn alatilẹyin Ọba Jimọh Ọlanipẹkun, Ataọja tiluu Oṣogbo ni wọn jade sita lọpọ yanturu laaarọ oni lati fi ẹhonu nla han wi pe awọn ko nii gba ẹnikẹni laaye lati rọ ọba wọn n'ipo, nitori pe oun l'awọn n fẹ.
 
Awuyewuye lo ti n lọ labẹlẹ wi pe awọn kan n gbero lati rọ Ọba Jimọ Ọlanipẹkun l'oye lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
 
Oriṣiriṣi patako ifẹhonuhan ti a mọ si 'Placards' l'awọn olufẹhonu han gbe sita lonii, nibi ti wọn ti n jẹ ko di mimọ pe Ọba Ọlanipẹkun l'awọn fẹ n'ipo naa, nitori pe awọn nigbagbọ ninu ẹ.
 
Ninu awọn patako naa ni wọn ti kọ ọ pe 'Ẹ fura o, Ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ da rukedurdo silẹ niluu Oṣogbo', 'Ọba JimọhAbidemi Oyetunji Ọlanipẹkun, Laaroye keji la fẹ. Ki Kabiyesi pẹ lori itẹ' ati awọn miran.
 
 
Bo tilẹ jẹ pe Ismail Omipidan to jẹ amugbalẹgbẹ gomina ti sọ tẹlẹ pe ko si otitọ ninu awuyewuye naa wi pe ijọba fẹẹ rọ Ataọja loye, ṣugbọn sibẹ, awọn kan l'awọn ko gbagbe, nitori pe ọrọ oṣelu.
 
Omipidan sọ pe awọn alaimọkan, awọn ika eeyan ni wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri wi pe wọn fẹẹ rọ Ọba naa loye, eyi to ni ko si otitọ kankan nibẹ.
 
O wa gba igbimọ Osogbo Action Committee lamọran lati ma ṣe kọ ẹyin araalu si Gomina Adegboyega Oyetola ninu ọrọ to wa nilẹ.
 

A gbọ pe igbimọ Osogbo Action Committee naa, nipasẹ olori wọn, Ajadi Badmus ti kọwe si gomina wi pe awọn ti mọ nipa wi pe wọn fẹẹ rọ ọba naa loye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI