Oludije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ti jẹ ko di mimọ pe oun ko f'igba kan ya owo lati fi gbọ bukata ipinlẹ Anambra lakoko toun wa gẹgẹ bi gomina.
Peter Obi lo sọrọ naa l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii niluu Abuja, nibi eto kan ti ileeṣẹ amohunmaworan ti ARISE ṣagbatẹru ẹ.
Ninu ọrọ ẹ, o sọ pe
“Lasiko mi gẹgẹ bi gomina tẹlẹri, ọdun mẹjọ ni mo fin sin ilu. Bi ẹ ba lọ si ipinlẹ naa, ẹ maa ṣakiyesi wi pe mi o ya owo l'ọwọ ẹnikẹni tabi ileeṣẹ kankan lorileede Naijiria. Wọn ko tii pe mi ri lati fọrọ wa mi lẹnu wo, tabi sọ pe owo kan sọn.
“Lọjọ ti mo gbe ijọba silẹ, mi o jẹ agbaṣẹṣe kankan to ti pari iṣẹ rẹ lowo, mi o jẹ owo ifẹyinti, ajẹẹlẹ, ẹtọ, tabi owo oṣu. Ni banki mẹta ti ipinlẹ naa n lo, Access, Diamond ati Fidelity, owo to le ni aadọta miliọnu ni mo fi silẹ.
“Mi o ya owo ri, mo sin ilu tọkantọkan, mo si fi owo wọn silẹ lai yọ nnkankan.”
No comments:
Post a Comment