Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtalelogun kan, Yakub Yusuf, ẹni to ṣẹṣẹ jade l'ẹwọn lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.
Oṣu to kọja la gbọ pe Yakub lọ jale nileeṣẹ ijọba to wa lagbegbe Alausa, Ikẹja, ti wọn si lọ foju rẹ ba le ẹjọ, nibi ti wọn ti juu sẹwọn oṣu kan gbako.
Ajọ eleto iranlọwọ kan ti kii ṣe ti ijọba, iyẹn Non-governmental organzation la gbọ pe wọn lọ gba Yakub silẹ, lẹyin ọsẹ meji to ti wa l'ẹwọn, ko to jade.
Ko tii ju bii wakati meji ti wọn sọ pe Yakub gba ominira, ti wọn lo tun gba ileeṣẹ pannapanna lọ, nibi to tun ti lọ jale miran, ti ọwọ si tẹ ẹ.
Benjamin Hundeyin fi ye wa pe CSP Olayinka Egbeyemi ti tare Yakub si ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwadii, iyẹn State Criminal Investigation Department (SCID) fun iwadii kikun.
No comments:
Post a Comment