Lẹyin ọsẹ marun-un, ijọba Kwara ṣi ile-ẹkọ COED pada - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 28, 2022

Lẹyin ọsẹ marun-un, ijọba Kwara ṣi ile-ẹkọ COED pada


Ijọba Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede ṣiṣi ile ẹkọ awọn olukọni, iyẹn College of Education tiluu Ilọrin, to si ni ki eto ẹkọ bẹrẹ loju ẹsẹ lai fi akoko ṣofo.
 
Ọsẹ marun-un gbako la gbọ pe ijọba Kwara fi ti ile ẹkọ naa pa, latari bi wọn ṣe sọ pe awọn akẹkọọ kan ba awọn ohun elo inu ọgba ile ẹkọ naa jẹ.
 
Nigba to n kede ṣiṣi ile ẹkọ naa pada, kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ giga, Ọmọwe Alabi Afees Abọlọrẹ jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe ṣi ile ẹkọ, ko ṣẹyin ipade alaafia to waye laaarin awọn alaṣẹ ile ẹkọ ọhun, awọn olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ ati ijọba lori itẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI