Ko ṣẹlẹ ri! Kasnaty Sugar fẹẹ fi ẹbun ọdun tọrẹ f'aadọfa arugbo lori Oke Olumọ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 28, 2022

Ko ṣẹlẹ ri! Kasnaty Sugar fẹẹ fi ẹbun ọdun tọrẹ f'aadọfa arugbo lori Oke Olumọ l'Abẹokuta


Gbogbo eto lo ti pari patapata bayii fun gbajugbaja sọrọsọrọ oro redio nni, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar lati da aadọfa arugbo lọla niluu Abẹokuta.

Ọjọ Aje, Mọnde ni ilu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun yoo gbalejo ọpọ awọn arugbo, ẹlẹẹkeji iru ẹ.

Kaakiri ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ la gbọ pe awọn aadọfa arugbo naa ti n bọ lati gba ẹbun ọdun loriṣiriṣi, eyi ti ileeṣẹ Sugarlink Concepts ṣagbatẹru ẹ.

Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ,  ọdun keji ree ti eto naa bẹrẹ, eyi to waye lọdun to kọja ninu gbọngan ayẹyẹ ti Daktad to wa lagbegbe Quarry nitosi Post Office, Ibara niluu Abẹokuta ni awọn arugbo ti ko din ni mọkandinlọgọrun (99) ti jẹ anfaani.

Nibẹ ni agba oṣere tiata nni, Oloye ti gba ẹbun mọto bọginni Toyota Camry to ni ọyẹ ninu.


Lara awọn oṣere to wa nibẹ lọjọ naa ni Oloogbe Tafa Oloyede, Pa Ajirebi at'awọn miran, ti awọn alatilẹyin Kasnaty Sugar lorileede Naijiria ati loke okun ko gbẹyin nibẹ.

Gbọngan ayẹyẹ ti Olumọ to wa lagbegbe Ikija ni eto ọhun yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mọkanla owurọ.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo awọn arugbo to maa wa nibẹ lọjọ naa ni wọn maa gba aṣọ ọfẹ ati owo ti wọn yoo fi ran aṣọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI