Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe idanwo igbega lẹnu iṣẹ yoo bẹrẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ipinlẹ naa, lojuna lati gbe awọn ti igbega tọ si kuro ni ipo ti wọn wa lọ si ipele miran, pẹlu ẹkunwo owo oṣu wọn.
Eto igbega fọdun 2022 la gbọ pe yoo bẹrẹ lọjọ kẹjọ si ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla ti a wa yii ni gbogbo ẹka ileeṣẹ ijọba patapata, lai yọ ẹyọkan silẹ.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Hajia Habibat Anikẹ Yusuf lo sọ eyi di mimọ, to si ni gbogbo awọn ti igbega tọ si fọdun 2022 patapata ni yoo kopa ninu eto idanwo naa.
O ni awọn to le ni ẹgbẹrun meji, 2,069 ni yoo kopa ninu eto idanwo naa, to si rọ gbogbo wọn lati lọ gba iwe idanwo wọn lọwọ awọn aṣoju to wa ni ẹka ileeṣẹ ti wọn wa.
Bakan naa ni alaga naa ṣe ikilọ wi pe ki onikaluku awọn ti yoo kopa ninu eto idanwo naa tete ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe lasiko, nitori pe awọn ko nii tun idanwo ṣe fẹnikẹni nigba ti eto naa ba kasẹ nilẹ.
Bayii ni eto idanwo naa yoo ṣe lọ;
GL- 07-09 Tuesday 8th November. 2022 /12-2pm
GL- 10-12 Wednesday 9th November. 2022/12-2pm
GL -13-16 Thursday 10th November. 2022/12-2pm
SPECIAL GROUP GL- 17 Friday 11th November. 2022/10am-12noon.
O wa fi kun ọrọ rẹ wi pe Staff Development College, to wa niluu Ilọrin ni idanwo naa yoo ti waye, ati pe ki gbogbo awọn akopa tete de ibudo idanwo wọn ni wakati meji ṣaaju asiko idanwo, ki wọn le ṣe ayẹwo to yẹ fun wọn ko di pe wọn bẹrẹ.
Lara awọn ohun ti wọn yoo mu dani ni kaadi idanimọ wọn lẹnu iṣẹ, ohun ikọwe ati iwe idawo wọn.
O tun tẹnumọ ọn wi pe idanwo ifọrọjomitoro-ọrọ yoo, iyẹn Oral Interview yoo bẹrẹ lọjọ kẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2022, bẹrẹ lati aago mẹjọ aabọ aarọ ojoojumọ, eyi to ni awọn to wa ni ipele keje si ipele kẹtadinlogun ni yoo lanfaani lati kopa.
No comments:
Post a Comment