Idajọ to waye fi han pe ododo ṣi wa ni Naijiria - Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 28, 2022

Idajọ to waye fi han pe ododo ṣi wa ni Naijiria - Aderinokun


Oludije sipo aṣofin agba orile-ede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Oloye Olumide Aderinokun ti gbe oṣuba kare fun ile ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ to gbe kalẹ.

Lonii, ọjọ Aje, Mọnde ni ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ paṣẹ pe ki ajọ eleto idibo n'ipinlẹ Ogun, INEC fi orukọ Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ati gbogbo awọn oludije sipo oṣelu sinu iwe akọsilẹ, nitori pe wọn lẹtọọ lati dije du ipo ninu eto idibo ọdun 2023.

Aderinokun nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa sọ pe iwuri nla lo jẹ foun pẹlu idajọ naa, to si ni ohun awọn araalu ni ile ẹjọ jẹ.

O dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ fun aduro ti wọn lakoko ipenija to wọle tọ wọn, to si tun ni ẹyin onisuuru ni Ọlọrun wa.

Bẹ o ba gbagbe, lakoko eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP to waye, ibo 214 ni Oloye Aderinokun ni ninu ibo 216, eyi to fi jawe olubori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI