Ajọ aladani kan ti fẹsun jibiti kan aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria tẹlẹ, Bukọla Saraki, wi pe o ko owo to le diẹ ni igba ataabọ miliọnu naira, N252.3m, eyi to jẹ t'awọn oṣiṣẹ fẹyinti ipinlẹ naa jẹ lakoko to wa n'ipo gomina.
Gẹgẹ bi ẹsun ti ajọ naa ti wọn pe orukọ wọn ni Awareness Against Corruption and Social Vices Initiative fi kan Saraki niwaju ile ẹjọ, iyẹn National Industrial Court to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, wọn ni owo awọn oṣiṣẹfẹyinti ipinẹ Kwara ni gomina tẹlẹ naa ko jẹ.
Owo to tomiliọnu N252,295,265.00 ni wọn n sọ pe o ko sapo ara rẹ lakoko to wa n'ijọba laaarin ọdun 2003 si ọdun 2011.
Ẹ ka ẹkunrẹrẹ naa n'ibi: Idaamu tuntun de ba Saraki lori ẹsun jibiti
No comments:
Post a Comment