Inu ironu ati idaamu nla l'awọn ọmọ ati oloye ẹgbẹ alatako nni, Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara wa bayii, lori b'awọn ogbontari ninu ẹgbẹ wọn ṣe kede wi pe awọn ti lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
A gbọ pe awọn to ṣe pataki ninu ẹgbẹ PDP ni Obbo-Aiyegunlẹ to wa nijọba ibilẹ Ekiti, koda, ti a gbọ pe awọn oloye ẹgbẹ naa gb'ọkan le ni wọn fẹgbẹ silẹ lojiji, ti wọn si kede sita wi pe awọn ti ba APC lọ.
Wọn ni asiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa ni Obbo Aiyegunlẹ n ṣe ipade lọwọ l'awọn eeyan yii lọ, lati lọ darapọ mọ wọn, iyẹn l'Ọjọru, Wẹside to kọja tii ṣe ana.
Ojo Samuel Ṣọla to jẹ amugbalẹgbẹ pataki tẹlẹri fun alaga ijọba ibilẹ Ekiti, Ọnarebu Akintọba Fatigun la gbọ pe o lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọ sibẹ, lati kede wi pe awọn ti ṣetan lati ṣatilẹyin fun APC.
Awọn ọmọ ẹgbẹ miran ni Adelọdun Banjọ; Bamidele Sunday (aka Ọmọga); Oluwọle Sunday; Ojo Ajibọla; Ayọ Aina; Esan Friday; Ogunlẹyẹ Abiọdun; Falọdun Sunday, atawọn miran.
Nigba to n sọrọ lori erongba wọn lati darapọ mọ PDP, Bamidele Sunday ati Adelọdun Banjọ ti wọn gba ẹnu awọn yooku sọrọ jẹ ko di mimọ pe ọna ti Gomina AbdulRazaq AbdulRahman n gba ṣi akanṣe iṣẹ, paapaa iṣakoso rẹ n jẹ eyi to yanilẹnu, nitori pe kii ṣe ojusaaju ẹnikẹni.
Wọn ni bo ṣe yẹ ki ijọba ri niyẹn, kii ṣe ki wọn maa ti ọrọ oṣelu bọ ohun ti wọn ba n ṣe, eyi ti yoo pada pa ipinlẹ, paapaa awọn araalu lara, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Siwaju sii ni wọn sọ pe idagbasoke to de ba awọn wọọdu meji to wa nijọba ibilẹ Ekiti, jẹ pataki idi t'awọn fi pinnu lati ṣatilẹyin fun APC, ati ipadasipo Gomina AbdulRazaq.
No comments:
Post a Comment