Ẹgbẹ oṣelu APC fi orukọ alẹnulọrọ mẹta ti yoo ṣakoso eto ipolongo idibo ni Kwara sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 24, 2022

Ẹgbẹ oṣelu APC fi orukọ alẹnulọrọ mẹta ti yoo ṣakoso eto ipolongo idibo ni Kwara sita


Laipẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ẹka ti ipinlẹ Kwara kede awọn alẹnulọrọ mẹta to ṣe gboogi ti yoo ṣakoso eyo ipolongo idibo wọn sita.

Awọn mẹta naa ni Amb Yahya Seriki to jẹ alakoso (Director General) eto ipolongo; Alaaji Abdullahi Samari toun jẹ igbakeji alakoso (Deputy Director General); ati Ọnarebu Florence Ọlasunmbọ Oyeyẹmi, toun jẹ agbẹnusọ.

Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Sunday Fagbemi sọ pe awọn nigbagbọ ninu awọn mẹta wọnyi, wi pe wọn yoo ṣe daadaa ni ipo ti wọn yan wọn si, nitori pe wọn ti fi idaniloju han tipẹtipẹ.

Bakan naa lo jẹ ko tun di mimọ pe ẹgbẹ naa yoo gbe orukọ awọn yooku ti wọn yoo wa ninu igbimọ ipolongo idibo sita laipẹ.

Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn mẹta wọnyi yoo ṣe ipade papọ pẹlu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI