Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ọlọpaa ipinlẹ Niger ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan, Clement Joseph ti wọn lo n fi iṣẹ iṣẹgun oyinbo, iyẹn dọkita lu awọn araalu ni jibiti.
Bo ṣe n lu jibiti owo naa la gbọ pe o tun n lu jibiti abẹ awọn obinrin, titi to fi f'awọn obinrin mẹrin ọtọọtọ loyun.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu yii la gbọ pe ọwọ tẹ Clement to n gbe ni Koropka, Chanchaga, ilu Minna.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Wasiu Abiọdun to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe o ti pẹ ti gendekunrin naa ti n pe ara ni dọkita, eyi to fi n lu awọn eeyan ni jibiti, lai mọ.
O ni awọn obinrin mẹrin to fun loyun lẹẹkan naa ni wọn fi ọrọ rẹ to awọn leti, t'awọn si ṣe iwadii rẹ finnifinni ko to di pe ọwọ tẹ ẹ, koda, a gbọ pe o tun ti ṣẹyun f'awọn obinrin laimọye igba.
Iroyin fi to wa leti pe ileese kan ti won pe orukọ ẹ ni ZUGA COINS INT'L ni Clement fi n gba owo lọwọ awọn eeyan lori ayelujara, to si ti gba owo to to ₦280,000 lọwọ ọkan lara awọn to ko sii lọwọ.
Ni bayii, a gbọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori ẹ.
No comments:
Post a Comment