Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu ibẹrubojo l'awọn ara ati olugbe ipinlẹ Ogun, paapaa awọn ara agbegbe Oke-Ata, Ṣoyọye, Ibara Orile, Rounder ati agbegbe ẹ wa lori bi awọn ajinigbe ṣe fi awọn agbegbe ọhun ṣe ibugbe, ti wọn si n ji awọn araalu gbe l'ọsan ati l'oru.
Ijọba ibilẹ Abẹokuta North l'awọn agbegbe yii wa. Bi awọn ajinigbe ṣe n wọle ji awọn eeyan gbe, naa ni wọn tun n dena de wọn lati ji wọn gbe. Koda, a gbọ pe ko sẹni to le sun oorun asundọkan ninu awọn to n gbe l'awọn agbegbe naa.
A tiẹ gbọ pe awọn ajinigbe yii ko bẹru awọn oṣiṣẹ eleto aabo, pẹlu awọn ohun ija oloro bii ibọn, ada abbl ti wọn n lo lati ṣiṣẹ buruku wọn.
Ohun ti a gbọ ni pe pupọ ninu awọn ajinigbe yii lo jẹ pe aṣọ ologun ni wọn n wọ lati fi ṣiṣẹ, ki aṣiri ma ba a tu wi pe ajinigbe ni wọn.
Pupọ awọn to n gbe l'awọn agbegbe ti a darukọ yii, to fi mọ awọn to n gbe nitosi Baraaki ologun ti Alamala ni wọn ti ko ẹru wọn kuro, ti wọn si lọ n gbe l'awọn agbegbe to jinna si ibi ti wọn wa tẹlẹ.
Wọn ni eto aabo agbegbe wọn ko fẹsẹ mulẹ to, nitori pe gbogbo owo ti wọn n pa, ati eyi ti wọn yoo pa lọdun bii marundinlogoji si asiko yii l'awọn ajinigbe n gba lọwọ wọn lẹẹkan ṣoṣo.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, nigba ti alukoro wọn, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọ pe ko si eyi to ṣokunkun si wọn ninu ohun t'awọn araalu n sọ nipa awọn ajinigbe ọhun.
“A ko le sọ pe a ko gbọ nipa ohun to n ṣẹlẹ l'awọn agbegbe yii, bo tilẹ jẹ pe iwadii ati igbesẹ ti n lọ lọwọ lati rọwọ to awọn ajinigbe naa. Mo tun fẹẹ fi da a yin loju pe ninu awọn ajinigbe yii ti wa lahamọ wa, ti wọn si ti n ran wa lọwọ ninu iwadii.”
No comments:
Post a Comment