Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla l'awọn ọmọ bibi ilu Ibara kaakiri agbaye wa, lori bi wọn ṣe n yọ ayọ ayẹyẹ ọgbọn ọdun ti Ọba Jacob Olufẹmi Ọmọlade, Olubara tiluu Ibara ti wa lori apeere awọn baba-nla rẹ.
Gbogbo eto lo si ti pari bayii, fun ẹgbẹ Bọbakẹyẹ ilu Ibara lati gbarada, pẹlu awọn eto ọlọkan-o-jọkan ti wọn ti la kalẹ fun ayẹyẹ igbade ọgbọn ọdun naa.
Ohun ti a gbọ ni pe lati inu oṣu kẹwaa, ọdun yii l'awọn ọmọ ilu Ibara ti wọn wa kaakiri agbaye ti n wa sile, fun ayẹyẹ ọgbọnọdun ti kabiyesi wọn gb'ade.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn gbajugbaja pedepede lori redio n'ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Adedeji Salami, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Skeledy Ọmọ Perry ṣe ṣalaye f'AWIKONKO, o ni ara ọtọ ni ayẹyẹ ajọdun igbade t'ọdun yii yoo gba waye.
Skeledy Ọmọ Perry, ẹni to tun jẹ alukoro ẹgbẹ Bọbakẹyẹ tiluu Ibara ṣapejuwe Olubara tiluu Ibara gẹgẹ bi ọkan pataki ninu ọba ipinlẹ Ogun ti amuyẹ rẹ ko ni afiwe.
Ọkunrin naa fi kun ọrọ rẹ pe eto naa bẹrẹ lati ọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2022 yii, ati pe Oluwo Ifa ilu naa, Oloye Adeleke Fagbemi Fagbenro Amusan, Ọba Kubua, awọn Oloye, awọn Baalẹ, ni wọn yoo lewaju gbogbo ọmọ ilu Ibara tile-toko lọ si Ibara Olosun, lati lọ fi ifẹ han si Oriade to sun sibẹ, iyẹn Ọba Adubiiwaji lati wure fun ilọsiwaju ilu Ibara Olosun.
Alukoro ẹgbẹ Bọbakẹyẹ ilu Ibara ni ko tan sibe, o ni lara eto ti o tun wa naa tun ni pe awọn oloye, awọn ọlọja ati gbogbo awọn ọmọ ilu yoo tun wolẹ.
Irun Jimọ yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu yii ni Mọṣalaṣi Jimọ to wa ni Omida niluu Ibara, iyẹn nitosi aafin ọba ilu Ibara.
O tẹsiwaju pe ọjọ Abamẹta, Satide, tii ṣe ọjọ kejila ni Ọba Ọmọlade yoo fi awọn oloye tuntun jẹ niluu Ibara; ti awọn oloye at'awọn ọmọ ilu si lọ ṣe isin idupẹ ajọdun ni ṣọọṣi St. Andrew to wa ni Omida.
Bakan naa lo tun fi kun un pe lọjọ Aje, Mọnde, to jẹ ọjọ kọkanla, oṣu yii ni gbajugbaja agba olori Fuji to filuu Abẹokuta ṣe ibugbe naa, Alaaji Ṣẹfiu Alao Adekunle, Agba Orin yoo dalubolẹ f'awọn eeyan, ti awọn eeyan jankanjankan yoo si pesẹ lati fi ẹsẹ rajo.
Salami wa fi kun ọrọ rẹ pe ipa ti ẹgbẹ Bọbakẹyẹ yoo ko lọjọ aṣekagba yii ko nii kere rara.
No comments:
Post a Comment