Gbogbo awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ fasiti ti wọn wa labẹ ẹgbẹ Academic Staff Union of Universities, ASUU ni wọn ti gba ẹkunrẹrẹ owo oṣu ti oṣu kọkanla, ọdun ti a wa yii.
AWIKONKO gbọ pe owo ajẹẹlẹ ti ijọba apapọ jẹ ẹgbẹ ASUU lati bi oṣu mẹjọ sẹyin ni ijọba apapọ ko tii sọrọ le lori lati mọ igba ti wọn yoo san owo ajẹẹlẹ naa.
Ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa to wa ni fasiti Bayero, eyi to wa niluu Kano, ipinlẹ Kano lo sọ eyi di mimọ niluu Abuja, laaarọ oni, Ọjọru, Wẹsidee.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
“Ninu awọn ọmọ ẹgbẹ wa ti bẹrẹ sii gba owo oṣu wọn, mo si le f'idi rẹ mulẹ wi pe a ti gba owo oṣu wa lẹkunrẹrẹ fun oṣu kọkanla ti a wa yii. Ju gbogbo rẹ lọ, ijọba ko tii san owo oṣu ajẹẹlẹ wa.”
Ohun ti a gbọ ni pe ijọba apapọ ko fẹẹ san owo oṣu f'awọn oṣiṣẹ naa, eyi to mu ki wọn gun le iyanṣẹlodi.
No comments:
Post a Comment