Alaga lapapọ fẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), Oloye Ralph Okey Nwosu ti jẹ ko di mimọ pe bi gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ṣe loun fẹẹ polongo ibo fun gomina to jade lati inu ẹgbẹ wọn, Biyi Otẹgbẹyẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ oṣelu.
Nwosu lo sọrọ naa niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja, nibi ipade awọn oniroyin to ṣe fun ipalẹmọ ipolongo idibo ọdun 2023 to wọle de.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Sẹnetọ Ibikunle Amosun to n ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC YORUBA, nibi to ti sọ pe Biyi Otẹgbẹyẹ loun yoo ṣatilẹyin fun ninu eto idibo gomina to n bọ lọna.
Nwosu sọ pe ọrọ oṣelu to wa nita lasiko yii, paapaa, eto idibo to n bọ lọna ko nii ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu, bi ko ṣe ẹni to okaju oṣuwọn lati dari araalu, paapaa ipinlẹ si ibi to yẹ.
Saaju ọrọ rẹ ni Alakoso ati oludasilẹ ṣọọṣi Jerusalem Ministry of God Worldwide, Wolii John Anifowoṣe ti sọ asọtẹlẹ wi pe ẹgbẹ ADC nikan ni ẹgbẹ ti Olọrun fọwọ si, wi pe wọn yoo mu ipinlẹ Ogun de ilọ ileri.
Wolii Anifowoṣe jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹ ADC ni Olọrun fẹẹ lo lati fi yi itan orileede Naijiria pada, to si ni ipinlẹ Ogun ni iṣẹ naa ti fẹẹ bẹrẹ.
O ni ohun gbogbo ni yoo maa ṣiṣẹ papọ fun rere ẹgbẹ naa, idi to fi ni Sẹnetọ Amosun ni Olọrun n lo lati polongo ẹgbẹ naa fun gbogbo agbaye, paapaa awọn ọmọ orileede Naijiria.
Nibẹ ni Oloye Nwosu ti sọ pe Onarebu Idowu Adelẹyẹ ni ojulowo akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu ADC n'ipinlẹ Ogun, bo tilẹ jẹ pe akọwe ipolongo pọ lẹgbẹ naa, ṣugbọn ni ti ipinlẹ, Adelẹyẹ ni.
No comments:
Post a Comment