Adanu nla! Muhammed Akanbi, Giwa fasiti Kwara jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 21, 2022

Adanu nla! Muhammed Akanbi, Giwa fasiti Kwara jade laye


Igbimọ alaṣẹ ati iṣakoso fasiti ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State University ti kede sita nipa ipapoda giwa wọn, Ọjọgbọn Muhammed Akanbi.
 
Ọjọgbọn Akanbi ni iroyin fi to wa leti wi pe o jade laye lọjọ Aiku, Sannde ana, ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2022, lẹyin aisan rampẹ to deedee kọluu.
 
Ninu atẹjade ti alabojuto eto igbaniwọle si fasiti Kwara fi sita, lo ti jẹ ko di mimọ pe ojiji ni iku Ọjọgbọn Akanbi jẹ f'awọn, nitori pe ohun ti wọn ko ro tẹlẹ ni.

Wọn wa rọ gbogbo awọn eeyan lati maa ranti awọn mọlẹbi oloogbe naa ati fasiti ọhun ninu adura ni gbogbo igba, paapaa lakoko ipenija nla yii.
 
Igbimọ fasiti naa ti wa ṣalaye pe awọn yoo kede eto isinku giwa wọn laipẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI