Minisita fọrọ eto iroyin ati aṣa lorileede Naijiria, Alaaji Lai Mohammed ti jẹ ko di mimọ pe ijọba orileede Naijiria ti tọwọ bọwe adehun pẹlu alaṣẹ ati alakoso ileese ikanni ayelujara ti Twitter, Elon Musk lati maa tọpinpin awọn to n loo lorileede yii.
O ni ijọba apapọ Naijiria ni bayii ni wọn tọpinpin bi awọn araalu ṣe n lo ikanni ni labẹ akoso tuntun ti Elon Musk.
Bẹ o ba gbagbe, lọdun 2021 ni ijọba apapọ gbegidina ikanni naa lorileede yii, pẹlu ẹsun wi pe wọn n lo o lati tako ijọba orileede yii, ati pe wọn fẹẹ fi da iṣọkan ilẹ Naijiria ru ni.
Nigba to n sọrọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, oni niluu Abuja, o ni ko si erongba wi pe awọn n gbegidina lilo ikanni naa mọ, niwọn igba ti asọyepọ ti wa laaarin ijọba Naijiria ati awọn alaṣẹ Twitter.
“
A ko ni erongba lati gbejidina lilo Twitter mọ. Ṣugbọn sibẹ, a ko le jokoo lati gba ki awọn ikanni ayelujara maa sọ orileede wa sinu rukerudo.
“Ẹ jẹ ki n sọ eyi fun un yin, a ti n tọpinpin gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ lori ikanni naa bayii. Kii ṣe erongba wa lati gbegidina lilo awọn ikanni ayelujara, rara.
“Ọpọ awọn eeyan lo ti pe wa, ti wọn ti sọrọ buruku si wa, wọn tun ti beere wi pe ki ni yoo ṣẹlẹ nigba ti iṣakoso miran ti gba Twitter.”
No comments:
Post a Comment