Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣ fi n sọ pe awọn ko tii ri gendekunrin, ọmọ ọdun mejilelogun ti ẹ n wo oju rẹ yii, Akinbọla Daniel Oluwapẹlumi, ẹni ti wọn ko mọ bo ṣe rin in.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ọhun, Yẹmisi Ọpalọla gbe jade lo ti sọ pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun yii ni Daniel ti jade nile, ti wọn ko si tii ri.
Ọpalọla sọ pe Daniel jade lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ, ti ko si pada sile latigba naa, o ni awọn to ta wọn lolobo jẹ ko di mimọ pe ọmọkunrin naa ko rin iru irin bẹẹ ri.
O ni wọn ko gburo rẹ sibikibi, bẹẹ si ni ko tii sẹni to le sọ pato wi pe ibi to wa ree.

Daniel ga ni iwọn bata marun-un, ko kọla, o gbọ ede Yoruba ati Geesi, bẹẹ lo si tun dundun niwọnba. Agbegbe Agbalẹ, Conducive Villa to wa niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun lo sọ pe Daniel n gbe.
O wa rọ ẹnikẹni to ba kofiri rẹ lati tete fi to ileeṣẹ wọn leti.
No comments:
Post a Comment