Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun n'ipinlẹ Ekiti, 'Biọdun Abayọmi Oyebanji ti kede Ọgbẹni Yinka Oyebọde gẹgẹ bi akọwe iroyin rẹ, to si ni iṣẹ rẹ bẹrẹ lai fi akoko ṣofo.
Lonii, ọjọ Aiku, Sannde ni wọn bura fun Oyebanji ati igbakeji rẹ, Oloye Monisade Afuyẹ niwaju Onidajọ Oyewọle Adeyẹye niluu Ado-Ekiti ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ n'ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Bamidele Agbẹdẹ bu ọwọ lu, lo ti sọ pe ẹni ti Gomina Oyebanji fẹ niyẹn, ati pe iṣẹ rẹ bẹrẹ loju ẹsẹ.
Yinka Oyebọde ni akọwe iroyin Gomina ana n'ipinlẹ naa, Kayọde Fayẹmi, to si ko ipa ribiribi ninu eto idagbasoke ipinlẹ naa.
Diẹ ree lara fọto bi ayẹyẹ ibura fun Gomina Biọdun Oyebanji ṣe lọ lonii, ọjọ Aiku, Sannde niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti:
No comments:
Post a Comment