Wọn bura fun Oyebanji, gomina karun-un n'ipinlẹ Ekiti lonii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 16, 2022

Wọn bura fun Oyebanji, gomina karun-un n'ipinlẹ Ekiti lonii


Lonii ni afẹfẹ ọtun tun fẹ nipinlẹ Ekiti pẹlu bi ijọba tuntun ṣe bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati tukọ ipinlẹ naa fun ọdun mẹrin gbako.

Itan tuntun lo tun balẹ lonii, ọjọ kẹrindilogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2022 lori bi wọn ṣe bura fun gomina tuntun ni ipinlẹ naa, Biọdun Oyebanji lati tẹsiwaju iṣejọba.

AWIKONKO gbọ pe Biọdun Oyebanji ni gomina karun-un ti ipinlẹ naa yoo dibo yan lati ọdun 1999 titi di akoko yii.

Oyebanji lo gba ijọba lọwọ Gomina Kayọde Fayẹmi, ẹni to jẹ alaga f'ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria.

Gomina tuntun naa pẹlu igbakeji rẹ, Oloye Monisade Afuyẹ ni wọn jọ bura fun ni gbagede Parapọ to wa niluu Ado-Ekiti.

Iwaju Onidajọ Oyewọle Adeyẹye ni Oyebanji ati igbakeji rẹ, Afuyẹ ti bura ni nnkan bi aago kan ku iṣẹju mẹjọ ọsan oni, ọjọ Aiku, Sannde.

Diẹ ree lara awọn to wa nibẹ:











No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI