Wọn ba oku meji ninu ọfiisi gbajumọ dọkita, o loun fi wọn ṣetutu ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 2, 2022

Wọn ba oku meji ninu ọfiisi gbajumọ dọkita, o loun fi wọn ṣetutu ni


Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣawari oku meji ti gbajugbaja dọkita kan, Abass Adio Adebọwale Adeyẹmi ri mọlẹ ninu ọfiisi rẹ to wa nijọba ibilẹ Kaiama, ipinlẹ Kwara.

Bẹ o ba gbagbe, Dọkita Abass, ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ọffa lo sẹku pa awakọ kan niluu Benin, ipinlẹ Ẹdo loṣu to kọja, iyẹn Emmanuel Yobo Agbovinuere.

Abass lo ta mọto fun Emmanuel, to tun pa a, to si lọ ju oku ẹ sinu igbo lagbegbe Otofure, loju ọna Benin si Eko, ti aṣiri rẹ si tu pẹlu mọto naa.


Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọkasanmi Ajayi gbe jade lonii, ọjọ keji, oṣu kẹwaa, o ni Abass ti jẹwọ pe oku ọrẹbinrin oun, Ifẹoluwa loun ri mọnu ọfiisi oun.

O ni agbegbe Tanke to wa niluu Ilọrin ni Ifẹoluwa n gbe, ibẹ si lo ti dawati ninu ọdun 2021.

Siwaju sii lo ni ọga ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe de ipinlẹ naa, CP Paul Odama lo pàṣẹ pe ki iwadii tubọ jinlẹ lori obinrin kan, Nofisat Halidu to dawati

Ninu iwadii lo ti sọ pe Abass to jẹ dọkita agba ni ọsibitu jẹnẹra ti Kaiama l'awọn lọ ja ilẹkun ọfiisi ẹ, ti wọn si fọ ilẹẹlẹ rẹ, nibi ti wọn ti ṣawari oku kan ninu saare to gbẹn sibẹ.

Bakan naa ni wọn tun ṣawari oku miran to jẹ ti Nọfisat Halidu ninu ile-ilẹ kan nini ọfiisi rẹ


Lara awọn nnkan miran ti wọn tun ri nibẹ ni foonu meji ninu baagi obinrin to tọju sinu ọfiisi rẹ, baagi obinrin meji, irun ti wọn n de sori (wig), pata obinrin at'awọn nnkan miran.

Ni bayii, a gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti kọwe si ileeṣẹ ọlọpaa Ẹdo lati fi Abass silẹ fun, ki wọn le fi ọrọ wa a lẹnu wo lori awọn nnkan ti wọn ri ni ọfiisi rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI