Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti tẹ baale ile, ẹni ogoji ọdun kan, Barnabas Abduneza, lori bo ṣe ṣeku pa ọmọ ikoko nipinlẹ naa, ti wọn tun loo ṣe mama ọmọ naa leṣe.
Abule kan ti wọn pe Kpasham, to wa nijọba ibilẹ Demsa, ipinlẹ Anambra la gbọ pe Barnabas n gbe, ṣugbọn ti iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun yii labule Kadamti.
Wọn ni ṣe ni Barnabas digun lọ ba iya ọmọ naa ati ọmọ ọhun lati ṣe wọn leṣe. Nibi ijakadi naa la gbọ pe ọmọ ọhun ti dagbere faye, ti iya rẹ si farapa yannayanna.
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Anambra, SP Sulaiman Nguroje, nigba to n f'idi iroyin ọhun mulẹ lonii, ọjọ Abamẹta, Satide, o jẹ ko di mimọ pe awọn ara abule naa ni wọn le Barnabas mu lakoko to n salọ, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
O ni awọn yoo foju ọkunrin naa ba ile ẹjọ laipẹ, lẹyin ti iwadii awọon ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.
No comments:
Post a Comment