Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission ti tẹ gbajugbaja amodedun ti wọn n pe ni Dick Jockey kan, Famotemi Toluwani Timothy lori ẹsun fifi orukọ gbajumọ olorin takasufee nni, Habeeb Okikiọla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Portable lu jibiti.
Timothy to f'ilu Ekiti ṣe ibugbe lọwọ tẹ l'ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun yii, lẹyin ti aṣiri ẹ tu sita.
A gbọ pe ṣe ni Timothy ṣe ayidayida orukọ Portable lori ikanni ayelujara ti Instgram pẹlu orukọ “Zazoo Omolalomi Portable”, to si n jẹ k'awọn eeyan ro pe ọkunrin naa ni.
Ọmọ bibi ilu Igede-Ekiti, ijọba ibilẹ Ifẹlodun naa la gbọ pe o pade ọkan lara awọn to lu ni jibiti, Adebayọ Adedimeji Lukman, ẹni to nile igbafẹ niluu Ọffa, ipinlẹ Kwara.
Wọn ni ṣe ni Timothy pe ara rẹ ni Portable fun Adebayọ, to si loun yoo wa kọrin fun wọn nibẹ, ati pe oun yoo gba miliọnu kan naira, ti adehun si wọ.
A gbọ pe Timothy gba ida ọgọrin ninu owo naa, to jẹ N790,000 naira, inu akanti ile ifowopamọsi kan ni Adebayọ san owo naa si, ti wọn si ṣe adehun pe yoo wa kọrin lọjọ kejidinlogun, oṣ keji, ọdun 2022 ti a wa yii.
Lẹyin ti wọn sọ pe Timothy gba owo ọhun, lo dinna gbogbo bi wọn ṣe le rii ba sọrọ, ti ko si yọju gẹgẹ bi adehun to ti gba owo ẹ. Eyi lo jẹ ki wọn lọ fi ọrọ rẹ to ileeṣẹ EFCC leti, ti wọn si bẹrẹ iwadii.
Ni bayii, ajọ EFCC ti sọ pe Timothy yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment