Otẹẹli Kwara ni lati wa ni ipo to yẹ ko wa - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 10, 2022

Otẹẹli Kwara ni lati wa ni ipo to yẹ ko wa - Ijọba


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede wi pe ki wọn ti otẹẹli ipinlẹ naa, iyẹn Kwara Hotel pa, to si ni otẹẹli naa ni lati wa ni ipo to yẹ ko wa, ko le ba ti asiko yii mu.

Lẹyin rogbodiyan to jẹyọ ni otẹẹli naa laipẹ yii, eyi to mu k'awọn oṣiṣẹ ibẹ f'ẹhonu han si owo oṣu ti ijọba ti jẹ wọn sẹyin, ti Gomina AbdulRazaq si ti san gbogbo rẹ, lo mu ki gomina paṣẹ pe ki wọn tii pa, paapaa lẹyin t'awọn aṣiri kan tu sita.
 
Ijọba ipinlẹ naa jẹ ko di mimọ pe otẹẹli Kwara n ṣaisan lọwọ, o si nilo itọju to pe ye lati ba ti igbalode mu.
 
Ọjọ Aiku, Sannde, ana ni ijọba Kwara paṣẹ pe ki wọn lọ ti otẹẹli ọhun pa, to si dari awọn oṣiṣẹ ibẹ si ileeṣẹ to n ri sọrọ idagbasoke okoowo ati imọ ayelujara, iyẹn Business, Innovation and Technology lati maa lọ ṣiṣẹ wọn nibẹ.
 
Gomina Abdulrazaq, nigba to n paṣẹ fun Kọmiṣanna fọrọ eto okoowo ati imọ ayelujara, Ọnarebu Ibrahim Akaje, o ni eyi yoo jẹ ki wọn ji otẹẹli naa dide pada kuro ni ipo oku to wa.

O ni ọpọ ileeṣẹ, ẹka ileeṣẹ ati ajọ lo rọ mọ otẹẹli naa, lara wọn si ni Harmonby Holdings wa, to si ni gbogbo ti ọrọ naa kan ni wọn yoo jokoo ipade lati ṣo asọyepọ lori idagbasoke ati itẹsiwaju otẹẹli naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI