Ṣẹnkẹn bayii ni inu ẹgbẹ awọn iyawo awọn ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara n dun nigba ti Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq kede wi pe awọn naa ti jẹ anfaani si eto Owo Iṣowo to n lọ lọwọ.
Ẹgbẹ naa labẹ agboorun ti wọn pe ni Police Officers’ Wives Association (POWA) lo jẹ anfaani yii, lati fi kun owo ti wọn fi n ṣowo, ki eto ọrọ aje wọn tun le lọ s'oke si, paapaa lati jẹ ki eto ọrọ aje ipinlẹ naa dagbasoke.
Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ọrọ naa jade sita nigba ti awọn ẹgbẹ naa tẹwọ gba owo wọn ti ijọba n pin kaakiri labẹ iṣakoso Kwara State Social Investment Programmes (KWASSIP) ti wọn tun n pe ni Owo Iṣowo.
Ẹgbẹrun lọna ọgbọn obinrin ni wọn n jẹ ninu anfaani naa to n lọ lọwọ, eyi ti banki apapọ agbaye ṣagbatẹru ẹ
Funra Gomina AbdulRahman AbdulRazaq la gbọ pe o fi owo naa le awọn iyawo awọn ọlọpaa yii lọwọ lati le mojuto pe lotitọ ni wọn jẹ anfaani naa.
No comments:
Post a Comment