Ọpẹ o! Ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye mọkanla ko s'ọwọ ọlọpaa n'Ijoko Ọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 16, 2022

Ọpẹ o! Ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye mọkanla ko s'ọwọ ọlọpaa n'Ijoko Ọta


Orin ọpẹ l'awọn ara agbegbe Sango, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta n'ipinlẹ Ogun mu s'ẹnu nigba ti wọn gbọ pe ọwọ palaba ọmọ egbẹ okunkun Aiye ti ko din ni mọkanla ti segi, ti wọn si ti wa lahamọ ọlọpaa.
 
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kọkanla, oṣu yii lọwọ tẹ gbogbo wọn, nibi ti wọon ti n palẹmọ lati da wahala miran silẹ.
 
Wọn l'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ni wọn n fi ojoojumọ da wahala silẹ lagbegbe naa, eyi to mu k'awọn araalu wa ninu ibẹrubojo ati ainifọkanbalẹ.
 
Mọṣhood Owolabi, Ọlayẹmi Arukudu, Yusuf Ọlajide, Ibukun Adeoye, Yọmi Samson, Faruk Salami, Olukunde Isaac, David Nwuzor, Nwanah Samuel, Ogunrinde Ganiyu ati Chukwuemeka l'awọn tọwọ tẹ naa.
 
Olobo kan ni wọn lo ta awọn ọlọpaa wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wa ni ojule kẹtala, adugbo Adura, Ijoko nibi ti wọn ti n ṣe ipade bi wọn ṣe fẹẹ da wahala nla silẹ.
 
Loju ẹsẹ la gbọ pe ọga ọlọpaa Sango, SP Saleh Dahiru ti gbera pẹlu awọn ọlọpaa abẹ rẹ, pẹlu awọn ẹṣọ aabo So-Safe ati Amọtẹkun, to fi mọ Sifu Difẹnsi lati lọ sibẹ.
 
Nibẹ la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn meje, ti awọn yooku si juba ehoro. Awọn araalu ni iroyin fi to wa leti pe wọn pada ri awọn mẹrin yooku tọwọ tẹ mu.
 
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa sọ pe loju ẹsẹ tọwọ ti tẹ wọn ni wọn ti n ka boroboro wi pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun pọnbele l'awọn.
 
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni Igbo, Kokeeni, Kolorado ati Bonky.
 
Oyeyẹmi ni ọga awọon Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ẹgbẹ okunkun bẹrẹ iṣẹ iwadii lati rii pe wọn foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI