Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi lati ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu olori meji ọtọọtọ lọjọ kan ṣoṣo.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹrinla, ọsu kẹwaa, ọdun 2022 la gbọ pe Ọọni fẹẹ gbe iyawo tuntun meji.
Lẹyin oṣu bii meloo kan ti Ọọni gbeyawo pẹlu Olori Mariam Anako lati ilu Ebira, ipinlẹ Kogi, ati Olori Elizabeth Ọpẹoluwa Ogunwusi 'Akinmuda', eyi to waye ni Magodo nipinlẹ Eko, a tun gbọ pe igbeyawo meji ni yoo waye l'oṣu yii.
Tobi Phillips ati Ashley Adegoke la gbọ pe Ọọni fẹẹ gbe niyawo ko too pe ọdun mejidinlaadọta loke eepẹ.
Tobi Phillips lo kẹkọọjade ni fasiti ipinlẹ Eko ni ẹka eto ẹkọ Marine Science, to si tun ti figba kan ri jẹ Omidan to rẹwa julọ. Iroyin to tiẹ ti kọkọ gba igboro tẹlẹ ni pe obinrin yii ni yoo rọpo Olori Zainab Wuraọla, ẹni to loun ko ṣe mọ, to si jade kuro l'aafin.
Onimọ nipa eto owo ti a mọ si Chartered Accountant bni Ashley Adegoke, to si ni ajọ alaanu kan to fi n ṣaanu awọn alaini, eyi to pe ni Ashley Adegoke Foundation.
No comments:
Post a Comment