Ọba marun-un gb'ọpa aṣẹ ni Kwara lọjọ kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 31, 2022

Ọba marun-un gb'ọpa aṣẹ ni Kwara lọjọ kan ṣoṣo


Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ijọba ipinlẹ Kwara lati gbe ọpa aṣẹ fun ọba marun-un ọtọọtọ ti awọn araalu f'ọwọ si, l'awọn ilu ti wọn ti fẹẹ j'ọba.

Awọn ọba tuntun naa ni: Oniṣapa tiluu Iṣapa, Ọba Oluwagbenga Adefioye n'ọba ibilẹ Ekiti; Olu tiluu Apakere, Ọba Isiaka Ismail Ọderinde; Alahun tiluu Ahun, Ọba Afeere Idowu Ogunlẹyẹ, to wa n'ijọba ibilẹ Ifẹlodun. Gbogbo awọn ọba wọnyii la gbọ pe ipo kẹrin (4th Class) ni wọn wa.

Ọba Fatai Talabi, Aala tiluu Ilala to wa n'ijọba ibilẹ Irẹpọdun ati Ọba Owolabi Kayọde Micheal, Alare tiluu Isare Opin n'ijọba ibilẹ Ekiti. Awọn wọnyi la gbọ pe wọn wa ni ipo kẹta (3rd Class).

Gẹgẹ bi atẹjade ti kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ n'ipinlẹ naa, Ọnarebu Lafia Aliyu Kora-Sabi fi sita, o ni o ti di dandan lẹyin ọpọ ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn ti wọn fẹẹ gbe ọpa aṣẹ fun yii, lati kede wọn gẹgẹ bi ojulowo ọba to tọ s'awọn ipo ọhun.

O tẹsiwaju pe Ọjọru, ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun yii ni ayẹyẹ eto gbigba ọpa aṣẹ ati iwe ẹri naa yoo waye f'awọn ọba to wa ni ipele kẹrin, nigba ti awọn to wa ni ipele kẹta yoo gba ọpa aṣẹ ati iwe ẹri l'ọjọ kẹrin ati ọjọ karun oṣu kọkanla, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI